Martin Auer
Ogun Ajeji
Stories for Peace Education

Ogun Ajeji

Emi Olajumoke Israel ni mo tumo e ni ede Yoruba

Ni igba kan ni ile jijina rere, awon orile ede meji kan wa ti won npe ni “Ile Ihin, ati Ile Ohun”. Awon orile ede mejeji wa ni egbe araa won. Awon orile ede miran yi won ka, awon bii Ile Jijina ati Ile Itosi, sugbon itan wayi da lori ile Ihin ati ile Ohun.

Omiran Alagbara kan wa ni ile-ihin oun nii se adari orile ede naa. Ni ojo kan, omiran alagbara yii pe awon eniyan ile re jo lati bawon soro, o wipe awon ara ilu ile ohun tii se ilu odikeji ngun awon garagara, awon o sile joko lasan maa wo won niran lai mase ohun kohun nipa re. o wi bayi pe-----

“Won wa ni itosi wa to bee gee ti a ko le ri imu mi, won ti sun wa titi a siti sun kan ogiri, won ko si se tan lati dehin, ki a le ni ominira. Sugbon ti won ba ko jale lati gba lero, a o fun won lele. Awa ko fe ogun, a ko si fe ote rara, ti o base nipa tiwa ni, alaafia ni yio maa joba titi, sugbon won ko fe bee, ti won ba si ko lati sun siwaju, awa yio sigun siwon, awa ko ni fun won ni aaye lati sigun lewa lori, a koni fi emi awon omo wa sofo lasan, ki awon obirin wa ma baa di opo osangangan, ati papa ki awon omo wa ma ba di omo alaini baba. Nitori naa, eyin ara, ki aba le daabo bo ara wa, ati awon omo wa, ati ki a le daabo bo alaafia ile wa, mo sigun le ilu ile-ohun”.

Rudurudu baa awon ara ilu ile-ihin, enu si ya won lopolopo to bee gee ti won nwoju araa won, won nwoju omiran alagbara, won si nwo awon Jagunjagun won ati awon ihamora ogun ati awon ohun ija won. Won duro yi ilu naa ka, ti won fi idunu pariwo, won si nkigbe pe “ki ilu ile ihin pe titi, ki ilu ile ohun si subu lule”. Eyi ni ariwo ti awon omo ogun ile ohun npa. Beeni ogun bere.

Ni ojo naa ni awon omo ogun ile ihin re odi ilu ile ohun koja. O je iran ti o lagbara ti o si bani leru. Nitoripe awon keke ogun naa dabi omiran eja nla, won si nte ohunkohun to bawa lona run. Won nyin awon ado oloro won si nfon awon majele sinu afefe, awon ado oloro yii si nfon gbogbo nkan ka, to bee gee to fi jepe ko si ibuso kan ti won ba koja, egbegberun ohun abemi ni on subu lule ku.

Awon ewe tutu ti o rewa wa niwaju won sugbon eyin nsofo lo.

Gbogbo oju sanmo dudu ni gbogbo ibi ti awon oko ofurufu ti nfo, gbogbo awon eniyan to wa nisale doju bole sile, jinijini si bo won nitori ariwo ati iro ogun ti won gbo, awon ado oloro si njabo si gbogbo ibi ti ojiji ba wa.

Laarin awon oko Jagunjagun ofurufu nlanla, ati awon keekeke, awon oko ologun ori ile ti won po lo rere, awon jagunjagun naa wo awon ewu irin ti o fi jepe ibon tabi awon ohun ija miran o lee ran won. Awon jagunjagun naa gbe awon ohun ija lowo, awon ibon nlanla ti ina njade ninu won. Bayi ni awon omo ogun ile ihin se titi tiwon si nwonu ile ohun lo pelu ireti lati te gbogbo ohun ti won bari run. Sugbon ohun ti o yani lenu ni wipe won ko ri enikeni.

Ni ojo kini, won wonu ilu ile ohun ni ibuso mewa, ojo keji ogun ibuso, ojo keta ni won re omi nla ilu naa koja. Ni gbogbo ibi ti won de, ohun ti won ti ri ni abule ofifo, oko ati awon ile ise ti ko si enikeni nibe, bee ni won npariwo “e wa gbogbo ayika, won ti sapamo ni, ki won le baa gbona eburu yo si wa latehin, e wa gbogbo ahere ati gbogbo inu aba.” Awon omo ogun bere si ni wa gbogbo ayika, sugbon awon ohun ti won ri koju awon iwe bii iwe idanimo, iwe iwako, iwe ojo ibi, awon iwe awon omo ile-iwe ati bee bee lo. Awon iwe to ni aworan, won ti fa awon aworan naa jade lara awon iwe yi, ko si ye won rara ohun ti gbogbo awon nkan wonyi tu mo si.

Wahala nla kan ti o tun koju won nipe gbogbo awon akori ti won gbe sona lati toka si awon ona kookan ni won ti daru, won gbe awon miiran kuro, won pa awon omiran re, won gbe awon miiran sibi ti o lodi, sugbon awon miran wa ni ibi toto, to bee gee ti won o fi le gbekele, eyi ni o je ki awon omo ogun ilu ile-ihin bere sini pooyi, ti won ko le mo ona ti won maa gba mo, won bere si ni fon ka lai moo ibi ti won ma gba. Eyi lo mu ki opo adari awon omo ogun niki won maa fi keke ogun wa awon omo ogun awon kiri, eyi naa lo si mu ki omiran alagbara ti o je adari orile-ede ti o sigun lo wa awon omoran ati amoye lati ya aworan ilu naa.

Nigbati odi ojo kerin, awon omo ogun naa mu elewon oju ogun won akoko, eniti oruko re nje Johannu Simiiti. Okurin yi kii se ologun rara, ara ilu lasan ni, olu ti o ma nhu sara igi ni oun ma nsa kiri ninu igbo nitie. Omiran alagbara pase ki won mu wa ba oun, ki oun funra oun fi oro wa lenu wo, sugbon okunrin naa ni oun ko mo ibi ti awon omo ogun ilu ile-ohun wa, lehin ojo die, won ti mu to egberun eniyan, eyi ti gbogbo won nje oruko kan kannaa, “Johannu tabi Jeeni Simiiti, ko sisi eyi ti oni iwe idanimo ninu won. Eleyi mu inu bi omiran alagbara yii.

Lakotan awon omo ogun yi gba ile akoko won, lehin naa ni won bere sii ko akori si awon adugbo nitori ti won fi awon aworan ilu naa ranse, sugbon awon asise po nibe nitoripe won nkanju, won tile fun awon adugbo miran ni oruko orisi meji, eyii lo wa jeki won bere sii sina.

Awon omo ogun naa nrin kaakiri pelu asaaju ti o mu aworan ilu naa lowo lai ribi ti won nlo, rudurudu wawa ninu ilu na nitori ohunkohun ko lo gege bi won ti se lero, ko sisi ohun ti sise. Gbogbo awon ile ise jankanjankan bii awon ile ise ibani soro lori ero, tabi ile ise monamona, ati beebee lo, gbogbo won lo dase sile. Sugbon omiran yii kede wipe oun ko gba didase sile laaye, nitori naa, ki onikaluku pada senu ise lesekese.

Awon eniyan yi pada senu ise, sugbon sibe, ohunkohun ko sise. Nigbati awon omo ogun ba lo bere wipe kilode ti awon eniyan osise, won a ni nitori wipe awon adari ati awon oga o wa sibi ise. Ko sisi bi won se fee da oga mo yato si omo ise, nitoripe oruko kannaa ni gbogbo won nje.

Nitori naa ni omiran alagbara tii se pase wipe awon ti won o ba lo oruko won, won a yinbon pa won bayi ni awon eniyan yi se tun lo ogbon alumo koroyi lati maape ara won ni oruko atijo, sugbon eleyi ko ran ohunkohun lowo.

Bi won ti se nwonu ilu naa lo, ni gbogbo nkan nle si, won ko tile ri onje ko jo po fun awon omo ogun, won ni lati maa ko onje wole lati inu ilu ile-ihin ni. Oko oju irin papa o tile sise, awon osise kan nduro kiri, won nlo, won mbo laisi ohun kan pato ti won nse. Gbogbo awon oga ti won mo bi ohun gbogbo ti nlo ti fara soko, ko sisi eni to mo ibi ti won wa.

Ko si enikeni to se ohun ibi Kankan si awon omo ogun yii ninu awon ara ilu yi, laipe won bere sini ba awon ara ilu sepo laini iberu wipe won le se won ni jamba. Awon araalu ti won ti fi ounje pamo fun awon jagunjagun tele bere si ni mu awon ohun ti won ni jade lati se pasiparo si ounje inu agolo awon omo ogun, nitori onje agolo yi ti su awon omo ogun yii.

Sugbon nigbati omiran alagbara yii tun gbo, o binu gidigidi, o si pase wipe awon omo ogun yi ko gbodo fi ibugbe won sile, afiti won ba njade lati lo sise pelu awon iko won, sugbon eleyi ko te awon omo ogun yii lorun rara.

Nigbeyin awon omo ogun ile-ihin gba olu ilu ile ohun, sugbon sibesibe bakannaa ni gbogbo nkan seri, bii tatehinwa. Ko si ami Kankan to toka si awon adugbo tabi ile-ise Kankan, ko si nomba tabi akole Kankan lara ile, ko si adari, tabi awon omoran Kankan lawon ibiise, ko si olopa, ko si si eni kankan nileese ijoba.

Omiran alagbara wa pinnu lati fi owo lile mu awon ara ilu yii. O pase ki gbogbo awon eniyan pada lo si ibi ise, oni enikeni ti won ba ri nile, won a yin ibon fun ni.

Oun funrara re wa lo si ile ise monamona o pase ki awon omo ogun ti won mo nipa ise monamona lo lati lo sibe, oni laarin wakati meji, ina gbodo tan, awon omo ogun yii bere sini pase fun awon osise, awon osise na si bere sini sa sokesodo lati se ohun ti won pase fun won. Sugbon otu bante lojasi, nitori ina yii ko tan. Eyi lo wa mu ki omiran alagbara yii pase fun awon osise yi wipe ti ko ba si ina laarin ogbon iseju, won a yinbon pa gbogbo won ni. Nitorina, laarin ogbon iseju ina monamona tan. Omiran alagbara yi tun lo si ile ise epo lati lo se bee gege.

Sugbon nigbati odijo keji, ina monamona yi ko tan, omiran yii pelu awon iko omo ogun tire wa fi ibinu losi ile ise monamona lati lo pa gbogbo awon osise ibe run, sugbon nigbati won de ibe, won ko ba enikeni, awon osise naa ti dara po mo awon osise miran

Omiran alagbara yi pase fun awon omo ogun lati ko awon egberun eniyan fun pipa.

Eleyi ko dunmo awon omo ogun yi ninu nitori wipe awon omo ogun yii ti darapo, won siti dore pelu awon araa ilu yi (nitori ogbon alumokoroyi ti awon ara ilu nlo pelu won). Won ni bawo lawon a se lo yinbon pa egberun eniyan laise. Awon iko ogun omiran yii wa lo sofun wipe inu awon omo ogun to ku ko dun si ase ti o pa yi ati papa wipe o le da wahala sile laarin awon omo ogun.

Omiran alagbara yi gba leta kan lati odo awon eniyan jankanjankan iluu re ni ilu ile-ihin, ti won si ko bayi wipe “Alagbara julo, oti sa ipaa re gege bi ogagun akoni, o si ti fihan pe ologbon ati oloye eniyan ni o, a si ki o gidigidi, o ku ajasegun. Sugbon nisisiyi, a pe o ki o maa pade bo sile ki o sifi awon eniyan ilu ile-ohun sile si tiwon. Won nna wa lowo pupo ju. Ti a ba le maa fi keke ogun le osise kookan kiri kia si ma hale ibon yinyin mo awon osise ati awon adari won, a je pe gbogbo wahala naa ko jasi nkankan mo. Jowo maa pada bo nile nitori orile-ede wa fe ilo re lopolopo”.

Nigba naa ni omiran alagbara yii pa ile awon omo ogun re mo, ti o si pase fun won lati ko gbogbo ikogun ti won ba le ko ninu ile-ohun, bayi ni o gba ilu re lo ti o si nwipe

“ah afun won ni ohun to tosi won. Ki lawon ope yi lese bayi, bawo ni won se fe mo onimo ero tabi dokita, laisi iwe eri. Nigbati ko si iwe idanimo bawo ni won se feda ara ati ohun ini won mo”. Bawo ni won se le gbe laisi iwe eri ile, tabi eri ile, laisi iwe irinna oko tabi ti olopa, bawo ni won sele se laisi aso olopa.

Gbogbo re naa, nitori pe ki won ma baa bawa jagun, o ma se o, awon ope eniyan.

Select afterword failed: Table 'at27023_peaceculture.Texts' doesn't exist